Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 31:14-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ati Kore, ọmọ Imna, ọmọ Lefi, adèna iha ila-õrun, li o wà lori awọn ọrẹ atinuwa Ọlọrun, lati pin ẹbọ ọrẹ Oluwa, ati ohun mimọ́ julọ.

15. Ati labẹ ọwọ rẹ̀ ni Edeni, ati Miniamini, ati Jeṣua, ati Ṣemaiah, Amariah, ati Ṣekaniah, ninu ilu awọn alufa, lati fun awọn arakunrin wọn li ẹsẹsẹ, li otitọ, bi fun ẹni-nla, bẹ̃ni fun ẹni-kekere.

16. Laika awọn ọkunrin, ti a kọ sinu iwe idile, lati ọmọ ọdun mẹta ati jù bẹ̃ lọ, fun olukuluku wọn ti o nwọ̀ inu ile Oluwa lọ, ìwọn tirẹ̀ lojojumọ, fun iṣẹ ìsin wọn, ninu ilana wọn, gẹgẹ bi ipa wọn;

17. Ati fun awọn alufa ti a kọ sinu iwe nipa ile baba wọn, ati awọn ọmọ Lefi, lati ẹni ogun ọdun ati jù bẹ̃ lọ, ninu ilana wọn, nipa ipa wọn:

18. Ati fun awọn ti a kọ sinu iwe, gbogbo awọn ọmọ kekeke wọn, awọn aya wọn, ati awọn ọmọkunrin wọn, ati awọn ọmọbinrin wọn, ja gbogbo ijọ enia na: nitori ninu otitọ ni nwọn yà ara wọn si mimọ́ ninu iṣẹ mimọ́.

19. Ati fun awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, ti o wà li oko igberiko ilu wọn ni olukuluku ilu, awọn ọkunrin wà nibẹ, ti a pè li orukọ, lati ma fi fun gbogbo awọn ọkunrin ninu awọn alufa, ati fun gbogbo awọn ti a kà ni idile idile ninu awọn ọmọ Lefi.

20. Bayi ni Hesekiah si ṣe ni gbogbo Juda, o si ṣe eyiti o dara, ti o si tọ́, ti o si ṣe otitọ, niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Kro 31