Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 30:1-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. HESEKIAH si ranṣẹ si gbogbo Israeli ati Juda, o si kọ iwe pẹlu si Efraimu ati Manasse, ki nwọn ki o wá sinu ile Oluwa ni Jerusalemu, lati pa ajọ irekọja mọ́ si Oluwa, Ọlọrun Israeli.

2. Nitoriti ọba ti gbìmọ ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo ijọ-enia ni Jerusalemu, lati pa ajọ irekọja mọ́ li oṣù keji.

3. Nitoriti nwọn kò le pa a mọ́ li akokò na, nitori awọn alufa kò ti iyà ara wọn si mimọ́ to; bẹ̃li awọn enia kò ti ikó ara wọn jọ si Jerusalemu.

4. Ọran na si tọ́ loju ọba ati loju gbogbo ijọ-enia.

5. Bẹ̃ni nwọn fi aṣẹ kan lelẹ, lati kede ká gbogbo Israeli, lati Beer-ṣeba ani titi de Dani, lati wá ipa ajọ irekọja mọ́ si Oluwa Ọlọrun Israeli ni Jerusalemu: nitori nwọn kò pa a mọ́ li ọjọ pupọ gẹgẹ bi a ti kọ ọ.

6. Bẹ̃li awọn onṣẹ ti nsare lọ pẹlu iwe lati ọwọ ọba ati awọn ijoye rẹ̀ si gbogbo Israeli ati Juda; ati gẹgẹ bi aṣẹ ọba, wipe, Ẹnyin ọmọ Israeli, ẹ tun yipada si Oluwa Ọlọrun Abrahamu, Isaaki, ati Israeli, On o si yipada si awọn iyokù ninu nyin, ti o sala kuro lọwọ awọn ọba Assiria.

Ka pipe ipin 2. Kro 30