Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 28:7-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ati Sikri, alagbara kan ni Efraimu, pa Maaseiah, ọmọ ọba, ati Asirkamu, olori ile, ati Elkana, ibikeji ọba.

8. Awọn ọmọ Israeli si kó ọkẹ mẹwa ninu awọn arakunrin wọn ni igbekun lọ, awọn obinrin, awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin, nwọn si kó ikogun pupọ lọdọ wọn pẹlu, nwọn si mu ikogun na wá si Samaria.

9. Woli Oluwa kan si wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Odedi: o si jade lọ ipade ogun ti o wá si Samaria, o si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nitoriti Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin binu si Juda li on ṣe fi wọn le nyin lọwọ, ẹnyin si pa wọn ni ipa-oro ti o de òke ọrun.

10. Ati nisisiyi ẹnyin npete lati tẹ awọn ọmọ Juda ati Jerusalemu ba fun ẹrú-kunrin ati ẹrú-birin nyin: ẹnyin kò ha jẹbi Oluwa Ọlọrun nyin, ani ẹnyin?

11. Njẹ nitorina, ẹ gbọ́ temi, ki ẹ si jọwọ awọn igbekun ti ẹnyin ti kó ni igbekun ninu awọn arakunrin nyin lọwọ lọ: nitori ibinu kikan Oluwa mbẹ lori nyin.

12. Nigbana li awọn kan ninu awọn olori, awọn ọmọ Efraimu, Asariah, ọmọ Johanani, Berekiah, ọmọ Meṣillemoti, ati Jehiskiah, ọmọ Ṣallumu, ati Amasa, ọmọ Hadlai, dide si awọn ti o ti ogun na bọ̀.

13. Nwọn si wi fun wọn pe, Ẹnyin kò gbọdọ mu awọn igbekun nì wá ihin: nitori wò o, awa ti jẹbi niwaju Oluwa, ẹnyin npete ati fi kún ẹ̀ṣẹ ati ẹbi wa: ẹbi wa sa tobi, ibinu kikan si wà lori Israeli.

14. Bẹ̃li awọn enia ti o hamọra fi awọn igbekun ati ikogun na silẹ niwaju awọn ijoye, ati gbogbo ijọ enia.

15. Awọn ọkunrin ti a pè li orukọ na si dide, nwọn si mu awọn igbekun na, nwọn si fi ikogun na wọ̀ gbogbo awọn ti o wà ni ihoho ninu wọn, nwọn si wọ̀ wọn laṣọ, nwọn si bọ̀ wọn ni bàta, nwọn si fun wọn ni ohun jijẹ ati ohun mimu, nwọn si fi ororo kùn wọn li ara, nwọn si kó gbogbo awọn alailera ninu wọn sori kẹtẹkẹtẹ, nwọn si mu wọn wá si Jeriko, ilu ọlọpẹ si ọdọ arakunrin wọn: nigbana ni nwọn pada wá si Samaria.

16. Li akokò na ni Ahasi ọba, ranṣẹ si awọn ọba Assiria lati ràn on lọwọ.

Ka pipe ipin 2. Kro 28