Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 28:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNI ogun ọdun ni Ahasi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu: on kò si ṣe eyiti o tọ́ li oju Oluwa, gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀:

2. Nitoriti o rìn li ọ̀na awọn ọba Israeli, o si ṣe ere didà fun Baalimu pẹlu.

3. O si sun turari li àfonifoji ọmọ Hinnomu, o si sun awọn ọmọ rẹ̀ ninu iná bi ohun-irira awọn orilẹ-ède, ti Oluwa ti le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.

4. O si rubọ, o si sun turari ni ibi giga wọnni, ati lori òke kekere, ati labẹ gbogbo igi tutu.

5. Nitorina Oluwa Ọlọrun rẹ̀ fi i le ọba Siria lọwọ; nwọn si kọlù u, nwọn si kó ọ̀pọlọpọ ni igbekun lọ ninu wọn, nwọn si mu wọn wá si Damasku. A si fi i le ọba Israeli lọwọ pẹlu, ti o pa a ni ipakupa.

6. Nitoriti Peka, ọmọ Remaliah, pa ọkẹ mẹfa enia ni Juda ni ijọ kan, gbogbo awọn ọmọ-ogun: nitoriti nwọn ti kọ̀ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ.

7. Ati Sikri, alagbara kan ni Efraimu, pa Maaseiah, ọmọ ọba, ati Asirkamu, olori ile, ati Elkana, ibikeji ọba.

8. Awọn ọmọ Israeli si kó ọkẹ mẹwa ninu awọn arakunrin wọn ni igbekun lọ, awọn obinrin, awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin, nwọn si kó ikogun pupọ lọdọ wọn pẹlu, nwọn si mu ikogun na wá si Samaria.

9. Woli Oluwa kan si wà nibẹ, orukọ ẹniti ijẹ Odedi: o si jade lọ ipade ogun ti o wá si Samaria, o si wi fun wọn pe, Kiyesi i, nitoriti Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin binu si Juda li on ṣe fi wọn le nyin lọwọ, ẹnyin si pa wọn ni ipa-oro ti o de òke ọrun.

10. Ati nisisiyi ẹnyin npete lati tẹ awọn ọmọ Juda ati Jerusalemu ba fun ẹrú-kunrin ati ẹrú-birin nyin: ẹnyin kò ha jẹbi Oluwa Ọlọrun nyin, ani ẹnyin?

Ka pipe ipin 2. Kro 28