O si ba ọba awọn ara Ammoni jà pẹlu, o si bori wọn. Awọn ara Ammoni si fun u li ọgọrun talenti fadakà li ọdun na, ati ẹgbãrun oṣuwọn alikama, ati ẹgbãrun ti barli. Eyi li awọn ara Ammoni san fun u, ati lọdun keji ati lọdun kẹta.