Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 27:4-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Ani o kọ́ ilu wọnni li òke Juda, ati ninu igbo, o mọ ile-odi ati ile-iṣọ.

5. O si ba ọba awọn ara Ammoni jà pẹlu, o si bori wọn. Awọn ara Ammoni si fun u li ọgọrun talenti fadakà li ọdun na, ati ẹgbãrun oṣuwọn alikama, ati ẹgbãrun ti barli. Eyi li awọn ara Ammoni san fun u, ati lọdun keji ati lọdun kẹta.

6. Bẹ̃ni Jotamu di alagbara, nitoriti o tun ọ̀na rẹ̀ ṣe niwaju Oluwa Ọlọrun rẹ̀.

7. Ati iyokù iṣe Jotamu ati gbogbo ogun rẹ̀, ati ọ̀na rẹ̀, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Israeli ati Juda.

8. Ẹni ọdun mẹ̃dọgbọ̀n ni, nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ọdun mẹrindilogun ni Jerusalemu.

9. Jotamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, nwọn si sìn i ni ilu Dafidi: Ahasi, ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Kro 27