Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 24:9-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nwọn si kede ni Juda ati Jerusalemu, lati mu owo ofin fun Oluwa wá, ti Mose iranṣẹ Ọlọrun, fi le Israeli lori li aginju.

10. Gbogbo awọn ijoye ati gbogbo awọn enia si yọ̀, nwọn si mu wá, nwọn fi sinu apoti na, titi o fi kún.

11. O si ṣe, nigbati akokò de lati mu apoti na wá sọdọ olutọju iṣẹ ọba nipa ọwọ awọn ọmọ Lefi, nigbati nwọn si ri pe, owo pọ̀, akọwe ọba ati olori ninu awọn alufa a wá, nwọn a si dà apoti na, nwọn a mu u, nwọn a si tun mu u pada lọ si ipò rẹ̀. Bayi ni nwọn nṣe li ojojumọ, nwọn si kó owo jọ li ọ̀pọlọpọ.

12. Ati ọba ati Jehoiada fi i fun iru awọn ti nṣiṣẹ ile Oluwa, nwọn si fi gbà àgbaṣe awọn oniṣọ̀nà okuta, ati awọn gbẹnàgbẹna, lati tun ile Oluwa ṣe, ati pẹlu awọn alagbẹdẹ irin, ati idẹ, lati tun ile Oluwa ṣe.

13. Bẹ̃li awọn ti o nṣiṣẹ ṣiṣẹ na, iṣẹ na si lọ siwaju ati siwaju li ọwọ wọn, nwọn si tun mu ile Ọlọrun duro si ipò rẹ̀, nwọn si mu u le.

14. Nigbati nwọn si pari rẹ̀ tan, nwọn mu owo iyokù wá si iwaju ọba ati Jehoiada, a si fi i ṣe ohun-elo fun ile Oluwa, ani ohun-elo fun ìsin ati fun ẹbọ, pẹlu ọpọ́n, ani ohun-elo wura ati fadakà. Nwọn si ru ẹbọ sisun ni ile Oluwa nigba-gbogbo ni gbogbo ọjọ Jehoiada.

15. Ṣugbọn Jehoiada di arugbo, o si kún fun ọjọ, o si kú, ẹni ãdoje ọdun ni nigbati o kú.

16. Nwọn si sìn i ni ilu Dafidi pẹlu awọn ọba, nitoriti o ṣe rere ni Israeli, ati si Ọlọrun, ati si ile rẹ̀.

17. Lẹhin ikú Jehoiada awọn ijoye Juda de, nwọn si tẹriba fun ọba. Nigbana li ọba si gbọ́ ti wọn.

18. Nwọn si kọ̀ ile Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, nwọn si nsìn òriṣa ati ere: ibinu si wá sori Juda ati Jerusalemu nitori ẹ̀ṣẹ wọn yi.

19. Sibẹ o rán awọn woli si wọn, lati mu wọn pada tọ̀ Oluwa wá; nwọn si jẹri gbè wọn; ṣugbọn nwọn kò fi eti si i.

Ka pipe ipin 2. Kro 24