Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 24:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ẸNI ọdun meje ni Joaṣi nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba ogoji ọdun ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Sibia ti Beer-ṣeba.

2. Joaṣi si ṣe eyiti o tọ li oju Oluwa ni gbogbo ọjọ Jehoiada, alufa.

3. Jehoiada si fẹ obinrin meji fun u, o si bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin.

4. O si ṣe lẹhin eyi, o wà li ọkàn Joaṣi lati tun ile Oluwa ṣe.

5. O si kó awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi jọ, o si wi fun wọn pe, Ẹ jade lọ si ilu Juda wọnni, ki ẹ si gbà owo jọ lati ọwọ gbogbo Israeli, lati tun ile Ọlọrun nyin ṣe li ọdọdun, ki ẹ si mu ọ̀ran na yá kankan. Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi kò mu ọ̀ran na yá kánkan.

6. Ọba si pè Jehoiada, olori, o si wi fun u pe, Ẽṣe ti iwọ kò bère li ọwọ awọn ọmọ Lefi, ki nwọn ki o mu owo ofin Mose, iranṣẹ Oluwa, lati Juda ati lati Jerusalemu wá, ati ti ijọ-enia Israeli fun agọ ẹri?

7. Nitori Ataliah, obinrin buburu nì ati awọn ọmọ rẹ ti fọ ile Ọlọrun; ati pẹlu gbogbo ohun mimọ́ ile Oluwa ni nwọn fi ṣe ìsin fun Baalimu.

8. Ọba si paṣẹ, nwọn si kàn apoti kan, nwọn si fi si ita li ẹnu-ọ̀na ile Oluwa.

Ka pipe ipin 2. Kro 24