Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 19:4-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Jehoṣafati si ngbe Jerusalemu: o nlọ, o mbọ̀ lãrin awọn enia lati Beerṣeba de òke Efraimu, o si mu wọn pada sọdọ Oluwa, Ọlọrun awọn baba wọn.

5. O si fi awọn onidajọ si ilẹ na, ninu gbogbo ilu olodi Juda, lati ilu de ilu,

6. O si wi fun awọn onidajọ pe, Ẹ kiyesi ohun ti ẹnyin nṣe! nitori ti ẹnyin kò dajọ fun enia bikòṣe fun Oluwa, ti o wà pẹlu nyin ninu ọ̀ran idajọ.

7. Njẹ nisisiyi, jẹ ki ẹ̀ru Oluwa ki o wà lara nyin, ẹ ma ṣọra, ki ẹ si ṣe e; nitoriti kò si aiṣedede kan lọdọ Oluwa Ọlọrun wa, tabi ojuṣaju enia, tabi gbigba abẹtẹlẹ.

8. Pẹlupẹlu ni Jerusalemu, Jehoṣafati yàn ninu awọn ọmọ Lefi, ati ninu awọn alufa, ati ninu awọn olori awọn baba Israeli, fun idajọ Oluwa, ati fun ẹjọ; nwọn si ngbe Jerusalemu.

9. O si kilọ fun wọn, wipe, Bayi ni ki ẹnyin ki o mã ṣe, ni ibẹ̀ru Oluwa, li otitọ, ati pẹlu ọkàn pipé.

Ka pipe ipin 2. Kro 19