Pẹlupẹlu ni Jerusalemu, Jehoṣafati yàn ninu awọn ọmọ Lefi, ati ninu awọn alufa, ati ninu awọn olori awọn baba Israeli, fun idajọ Oluwa, ati fun ẹjọ; nwọn si ngbe Jerusalemu.