Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 18:25-34 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Nigbana ni ọba Israeli wipe, Ẹ mu Mikaiah, ki ẹ si mu u pada sọdọ Amoni, olori ilu, ati sọdọ Joaṣi, ọmọ ọba.

26. Ki ẹ si wipe, Bayi li ọba wi, ẹ fi eleyi sinu tubu, ki ẹ si fi ọnjẹ ipọnju ati omi ipọnju bọ́ ọ, titi emi o fi pada bọ̀ li alafia.

27. Mikaiah si wipe, Ni pipada bi iwọ ba pada bọ̀ li alafia, njẹ Oluwa kò ti ọdọ mi sọ̀rọ. O si wipe, Ẹ gbọ́, ẹnyin enia gbogbo!

28. Bẹ̃li ọba Israeli ati Jehoṣafati, ọba Juda, si gòke lọ si Ramoti-Gileadi.

29. Ọba Israeli si wi fun Jehoṣafati pe, emi o pa aṣọ dà, emi o si lọ si oju ìja; ṣugbọn iwọ gbé aṣọ igunwà rẹ wọ̀. Bẹ̃li ọba Israeli si pa aṣọ dà: nwọn si lọ si oju ìja.

30. Ṣugbọn ọba Siria ti paṣẹ fun awọn olori kẹkẹ́ ti o wà lọdọ rẹ̀, pe, Ẹ máṣe ba ewe tabi àgba jà, bikòṣe ọba Israeli nikan.

31. O si ṣe, nigbati awọn olori kẹkẹ́ ri Jehoṣafati, ni nwọn wipe eyi li ọba Israeli, nitorina nwọn yi i ka lati ba a jà: ṣugbọn Jehoṣafati kigbe, Oluwa si ràn a lọwọ: Ọlọrun si yi wọn pada kuro lọdọ rẹ̀.

32. O si ṣe, bi awọn olori kẹkẹ́ ti woye pe kì iṣe ọba Israeli, nwọn yipada kuro lẹhin rẹ̀.

33. Ọkunrin kan si fa ọrun rẹ̀ laipete, o si ta ọba Israeli lãrin ipade ẹwu-irin, o si wi fun olutọju kẹkẹ́ rẹ̀ pe, Yi ọwọ rẹ pada, ki o mu mi jade kuro loju ìja; nitoriti mo gbọgbẹ́.

34. Ija na si pọ̀ li ọjọ na: pẹlupẹlu ọba Israeli duro ninu kẹkẹ́ rẹ̀ kọju si awọn ara Siria titi di aṣãlẹ: o si kú li akokò ìwọ õrun.

Ka pipe ipin 2. Kro 18