Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 16:9-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nitoriti oju Oluwa nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aiye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkàn pípe si ọdọ rẹ̀. Ninu eyi ni iwọ hùwa aṣiwere: nitorina lati isisiyi lọ ogun yio ma ba ọ jà.

10. Asa si binu si ariran na, o si fi i sinu tubu; nitoriti o binu si i niti eyi na. Asa si ni ninu awọn enia na lara li akokò na.

11. Si kiyesi i, iṣe Asa ti iṣaju ati ti ikẹhin, wò o, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli.

12. Ati li ọdun kọkandilogoji ijọba rẹ̀, Asa ṣe aisan li ẹsẹ rẹ̀, titi àrun rẹ̀ fi pọ̀ gidigidi: sibẹ ninu aisan rẹ̀ on kò wá Oluwa, bikòṣe awọn oniṣegun.

13. Asa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, o si kú li ọdun kọkanlelogoji ijọba rẹ̀.

14. Nwọn si sìn i sinu isa-okú, ti o gbẹ́ fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, nwọn si tẹ́ ẹ lori àkete ti a fi õrun-didùn kùn, ati oniruru turari ti a fi ọgbọ́n awọn alapolu pèse: nwọn si ṣe ijona nlanla fun u.

Ka pipe ipin 2. Kro 16