orí

  1. 1
  2. 2
  3. 3
  4. 4
  5. 5
  6. 6
  7. 7
  8. 8
  9. 9
  10. 10
  11. 11
  12. 12
  13. 13
  14. 14
  15. 15
  16. 16
  17. 17
  18. 18
  19. 19
  20. 20
  21. 21
  22. 22
  23. 23
  24. 24
  25. 25
  26. 26
  27. 27
  28. 28
  29. 29
  30. 30
  31. 31
  32. 32
  33. 33
  34. 34
  35. 35
  36. 36

Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 16 Yorùbá Bibeli (YCE)

Ìyọnu De bá Israẹli

1. LI ọdun kẹrindilogoji ijọba Asa, Baaṣa, ọba Israeli, gòke wá si Juda, o si kọ́ Rama, nitori ki o má ba jẹ ki ẹnikan ki o jade, tabi ki o wọle tọ̀ Asa, ọba Juda lọ.

2. Nigbana ni Asa mu fadakà ati wura jade lati inu iṣura ile Oluwa wá, ati ile ọba, o si ranṣẹ si Benhadadi, ọba Siria, ti ngbe Damasku, wipe,

3. Majẹmu kan wà larin temi tirẹ, bi o ti wà lãrin baba mi ati baba rẹ; kiyesi i, mo fi fadakà ati wura ranṣẹ si ọ; lọ, bà majẹmu ti o ba Baaṣa, ọba Israeli dá jẹ, ki o le lọ kuro lọdọ mi.

4. Benhadadi si gbọ́ ti Asa ọba, o si rán awọn olori ogun rẹ̀ si ilu Israeli wọnni, nwọn si kọlù Ijoni, ati Dani, ati Abel-Maimu, ati gbogbo ilu iṣura Naftali.

5. O si ṣe, nigbati Baaṣa gbọ́, o ṣiwọ atikọ́ Rama, o si dá iṣẹ rẹ̀ duro.

6. Ṣugbọn Asa ọba kó gbogbo Juda jọ; nwọn si kó okuta ati igi Rama lọ, eyiti Baaṣa nfi kọ́le; o si fi kọ́ Geba ati Mispa.

Wolii Hanani

7. Li àkoko na Hanani, ariran, wá sọdọ Asa, ọba Juda, o si wi fun u pe, Nitoriti iwọ gbẹkẹle ọba Siria, iwọ kò si gbẹkẹle Oluwa Ọlọrun rẹ, nitorina ni ogun ọba Siria ṣe bọ́ lọwọ rẹ.

8. Awọn ara Etiopia ati awọn ara Libia kì iha ise ogun nla, pẹlu ọ̀pọlọpọ kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin? ṣugbọn nitoriti iwọ gbẹkẹle Oluwa, on fi wọn le ọ lọwọ.

9. Nitoriti oju Oluwa nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aiye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkàn pípe si ọdọ rẹ̀. Ninu eyi ni iwọ hùwa aṣiwere: nitorina lati isisiyi lọ ogun yio ma ba ọ jà.

10. Asa si binu si ariran na, o si fi i sinu tubu; nitoriti o binu si i niti eyi na. Asa si ni ninu awọn enia na lara li akokò na.

Òpin Ìjọba Asa

11. Si kiyesi i, iṣe Asa ti iṣaju ati ti ikẹhin, wò o, a kọ wọn sinu iwe awọn ọba Juda ati Israeli.

12. Ati li ọdun kọkandilogoji ijọba rẹ̀, Asa ṣe aisan li ẹsẹ rẹ̀, titi àrun rẹ̀ fi pọ̀ gidigidi: sibẹ ninu aisan rẹ̀ on kò wá Oluwa, bikòṣe awọn oniṣegun.

13. Asa si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, o si kú li ọdun kọkanlelogoji ijọba rẹ̀.

14. Nwọn si sìn i sinu isa-okú, ti o gbẹ́ fun ara rẹ̀ ni ilu Dafidi, nwọn si tẹ́ ẹ lori àkete ti a fi õrun-didùn kùn, ati oniruru turari ti a fi ọgbọ́n awọn alapolu pèse: nwọn si ṣe ijona nlanla fun u.