Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 12:9-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Bẹ̃ni Ṣiṣaki, ọba Egipti, goke wá si Jerusalemu, o si kó iṣura ile Oluwa lọ, ati iṣura ile ọba; o kó gbogbo rẹ̀: o kó awọn asà wura lọ pẹlu ti Solomoni ti ṣe.

10. Rehoboamu ọba si ṣe asà idẹ ni ipò wọn, o si fi wọn le ọwọ olori ẹṣọ ti ntọju ọ̀na ile ọba.

11. O si ṣe, nigbakugba ti ọba ba si wọ̀ ile Oluwa lọ, awọn ẹṣọ a de, nwọn a si kó wọn wá, nwọn a si kó wọn pada sinu iyara ẹṣọ.

12. Nigbati o si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ, ibinu Oluwa yipada kuro lọdọ rẹ̀, ti kò fi run u patapata: ni Juda pẹlu, ohun rere si mbẹ.

13. Bẹ̃ni Rehoboamu ọba mu ara rẹ̀ le ni Jerusalemu, o si jọba: nitori Rehoboamu jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji nigbati o bẹ̀rẹ si ijọba, o si jọba li ọdun mẹtadinlogun ni Jerusalemu, ilu ti Oluwa ti yàn lati inu gbogbo ẹ̀ya Israeli, lati fi orukọ rẹ̀ sibẹ. Orukọ iya rẹ̀ si ni Naama, ara Ammoni.

14. O si ṣe buburu, nitori ti kò mura ọkàn rẹ̀ lati wá Oluwa.

15. Njẹ iṣe Rehoboamu, ti iṣaju ati ti ikẹhin, a kò ha kọ wọn sinu iwe Ṣemaiah, woli, ati ti Iddo, ariran, nipa iwe itan idile? Ọtẹ si wà lãrin Rehoboamu ati Jeroboamu nigbagbogbo.

16. Rehoboamu si sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a si sìn i ni ilu Dafidi: Abijah ọmọ rẹ̀ si jọba ni ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin 2. Kro 12