Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

2. Kro 10:10-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Awọn ipẹrẹ ti a tọ́ pẹlu rẹ̀ si sọ fun u wipe, Bayi ni iwọ o da awọn enia na li ohùn ti o sọ fun ọ, wipe, Baba rẹ mu àjaga wa di wuwo, ṣugbọn iwọ ṣe e ki o fẹrẹ diẹ fun wa; bayi ni ki iwọ ki o wi fun wọn, Ọmọdirin mi yio nipọn jù ẹgbẹ́ baba mi lọ.

11. Njẹ nisisiyi baba mi ti fi àjaga wuwo bọ̀ nyin lọrùn, emi o si fi kún àjaga nyin: baba mi fi paṣan nà nyin, ṣugbọn akẽke li emi o fi nà nyin.

12. Jeroboamu ati gbogbo awọn enia si tọ̀ Rehoboamu wá ni ijọ kẹta gẹgẹ bi ọba ti dá, wipe, Ẹ pada tọ̀ mi wá ni ijọ kẹta.

13. Nigbana ni ọba da wọn li ohùn akọ; Rehoboamu ọba si kọ̀ imọran awọn àgbagba silẹ.

14. O si da wọn li ohùn gẹgẹ bi imọran awọn ipẹrẹ, wipe, Baba mi mu àjaga nyin ki o wuwo, ṣugbọn emi o fi kún u; baba mi ti fi paṣan nà nyin, ṣugbọn emi o fi akẽke nà nyin.

15. Bẹ̃ni ọba kò si fetisi ti awọn enia na: nitori ṣiṣẹ ọ̀ran na lati ọwọ Ọlọrun wá ni, ki Oluwa ki o le mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ, ti o sọ nipasẹ Ahijah, ara Ṣilo fun Jeroboamu, ọmọ Nebati.

16. Nigbati gbogbo Israeli ri pe, ọba kọ̀ lati fetisi ti wọn, awọn enia na da ọba lohùn, wipe, Ipin kili a ni ninu Dafidi? awa kò si ni ini kan ninu ọmọ Jesse: Israeli, olukuluku sinu agọ rẹ̀: nisisiyi Dafidi, mã bojuto ile rẹ. Bẹ̃ni gbogbo Israeli lọ sinu agọ wọn,

17. Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli ti ngbe ilu Juda wọnni, Rehoboamu jọba lori wọn.

18. Nigbana ni Rehoboamu ọba ran Hadoramu ti iṣe olori iṣẹ-irú; awọn ọmọ Israeli si sọ ọ li okuta, o si kú. Ṣugbọn Rehoboamu ọba yara lati gun kẹkẹ́ rẹ̀ lati salọ si Jerusalemu.

19. Bẹ̃ni Israeli si ya kuro lọdọ ile Dafidi titi o fi di oni yi.

Ka pipe ipin 2. Kro 10