Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 9:8-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Iranṣẹ na si da Saulu lohùn wipe, Mo ni idamẹrin ṣekeli fadaka lọwọ́, eyi li emi o fun ẹni Ọlọrun na, ki o le fi ọ̀na wa hàn wa.

9. (Ni Israeli latijọ, nigbati ọkunrin kan ba lọ bere lọdọ Ọlọrun, bayi ni ima wi, Wá, ẹ jẹ ki a lọ sọdọ arina na, nitori ẹni ti a npe ni woli nisisiyi, on ni a npe ni arina nigba atijọ ri)

10. Nigbana ni Saulu wi fun iranṣẹ rẹ̀ pe, Iwọ wi rere; wá, jẹ ki a lọ. Bẹ̃ni nwọn si lọ si ilu na nibiti ẹni Ọlọrun nã gbe wà.

11. Bi nwọn ti nlọ si oke ilu na, nwọn ri awọn wundia ti nlọ fa omi, nwọn bi wọn lere wipe, Arina mbẹ nihin bi?

12. Nwọn si da wọn lohùn, nwọn si wipe, O mbẹ; wo o, o mbẹ niwaju nyin: yara nisisiyi nitoripe loni li o de ilu; nitoriti ẹbọ mbẹ fun awọn enia loni ni ibi giga.

13. Bi ẹnyin ti nlọ si ilu na, ẹnyin o si ri i, ki o to lọ si ibi giga lati jẹun: nitoripe awọn enia kì yio jẹun titi on o fi de, nitori on ni yio sure si ẹbọ na; lẹhin eyini li awọn ti a pè yio to jẹun. Ẹ goke lọ nisisiyi; lakoko yi ẹnyin o ri i.

14. Nwọn goke lọ si ilu na: bi nwọn si ti nwọ ilu na, kiye si i, Samueli mbọ̀ wá pade wọn, lati goke lọ si ibi giga na,

15. Oluwa ti wi leti Samueli ni ijọ kan ki Saulu ki o to de, wipe,

16. Niwoyi ọla emi o ran ọkunrin kan lati ilẹ Benjamini wá si ọ, iwọ o si da ororo si i lori ki o le jẹ olori-ogun Israeli awọn enia mi, yio si gbà awọn enia mi là lọwọ awọn Filistini: nitori emi ti bojuwo awọn enia mi, nitoripe ẹkun wọn ti de ọdọ mi.

17. Nigbati Samueli ri Saulu, Oluwa wi fun u pe, Wo ọkunrin na ti mo ti sọrọ rẹ̀ fun ọ! on ni yio jọba awọn enia mi.

18. Saulu si sunmọ Samueli li ẹnu-ọna ilu, o si wipe, Sọ fun mi, emi bẹ ọ, nibo ni ile arina gbe wà?

Ka pipe ipin 1. Sam 9