Iranṣẹ na si da Saulu lohùn wipe, Mo ni idamẹrin ṣekeli fadaka lọwọ́, eyi li emi o fun ẹni Ọlọrun na, ki o le fi ọ̀na wa hàn wa.