Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 8:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Oluwa si wi fun Samueli pe, Gbọ́ ohùn awọn enia na ni gbogbo eyi ti nwọn sọ fun ọ: nitoripe iwọ ki nwọn kọ̀, ṣugbọn emi ni nwọn kọ̀ lati jẹ ọba lori wọn.

8. Gẹgẹ bi gbogbo iṣe ti nwọn ṣe lati ọjọ ti mo ti mu nwọn jade ti Egipti wá, titi o si fi di oni, bi nwọn ti kọ̀ mi silẹ, ti nwọn si nsin awọn ọlọrun miran, bẹ̃ni nwọn ṣe si ọ pẹlu.

9. Njẹ nitorina gbọ́ ohùn wọn: ṣugbọn lẹhin igbati iwọ ba ti jẹri si wọn tan, nigbana ni ki iwọ ki o si fi iwà ọba ti yio jẹ lori wọn hàn wọn.

10. Samueli si sọ gbogbo ọ̀rọ Oluwa fun awọn enia na ti o mbere ọba lọwọ́ rẹ̀.

11. O si wipe, Eyi ni yio ṣe ìwa ọba na ti yio jẹ lori nyin: yio mu awọn ọmọkunrin nyin, yio si yàn wọn fun ara rẹ̀ fun awọn kẹkẹ́ rẹ̀, ati fun ẹlẹṣin rẹ̀, nwọn o si ma sare niwaju kẹkẹ́ rẹ̀.

12. Yio si yan olori ẹgbẹgbẹrun fun ara rẹ̀, ati olori aradọta; yio si yàn wọn lati ma ro oko rẹ̀, ati lati ma kore fun u, ati lati ma ṣe ohun elo-ogun rẹ̀, ati ohun elo-kẹkẹ́ rẹ̀.

13. On o si mu ninu ọmọbinrin nyin ṣe olùṣe ikunra õrun didùn, ati ẹniti yio ma ṣe alasè, ati ẹniti yio ma ṣe akara.

14. Yio mu ninu oko nyin, ati ninu ọgba ajara nyin, ati ninu igi olifi nyin wọnni, ani eyiti o dara julọ ninu wọn, yio si fi fun awọn ẹrú rẹ̀.

15. On o si mu idamẹwa ninu irugbin nyin, ati ọgbà ajara nyin, yio si fi fun awọn ẹmẹ̀wa rẹ̀ ati fun awọn ẹrú rẹ̀.

16. Yio mu awọn ẹrúkunrin nyin, ati ẹrubirin nyin, ati awọn aṣàyàn ọdọmọkunrin nyin, ati awọn kẹtẹkẹtẹ nyin, yio si fi nwọn si iṣẹ ara rẹ̀.

17. On o si mu idamẹwa ninu awọn agutan nyin: ẹnyin o si jasi ẹrú rẹ̀.

18. Ẹnyin o kigbe fun igbala li ọjọ na nitori ọba nyin ti ẹnyin o yàn: Oluwa kì yio gbọ́ ti nyin li ọjọ na.

Ka pipe ipin 1. Sam 8