Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 8:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati Samueli di arugbo, on si fi awọn ọmọ rẹ̀ jẹ onidajọ fun Israeli.

2. Orukọ akọbi rẹ̀ njẹ Joeli; orukọ ekeji rẹ̀ si njẹ Abia: nwọn si nṣe onidajọ ni Beerṣeba.

3. Awọn ọmọ rẹ̀ kò si rin ni ìwa rẹ̀, nwọn si ntọ̀ erekere lẹhin, nwọn ngbà abẹtẹlẹ, nwọn si nyi idajọ po.

4. Gbogbo awọn agbà Israeli si ko ara wọn jọ, nwọn si tọ Samueli lọ si Rama,

5. Nwọn si wi fun u pe, Kiye si i, iwọ di arugbo, awọn ọmọ rẹ kò si rin ni ìwa rẹ: njẹ fi ẹnikan jẹ ọba fun wa, ki o le ma ṣe idajọ wa, bi ti gbogbo orilẹ-ède.

6. Ṣugbọn ohun na buru loju Samueli, nitori ti nwọn wipe, Fi ọba fun wa ki o le ma ṣe idajọ wa, Samueli si gbadura si Oluwa.

7. Oluwa si wi fun Samueli pe, Gbọ́ ohùn awọn enia na ni gbogbo eyi ti nwọn sọ fun ọ: nitoripe iwọ ki nwọn kọ̀, ṣugbọn emi ni nwọn kọ̀ lati jẹ ọba lori wọn.

8. Gẹgẹ bi gbogbo iṣe ti nwọn ṣe lati ọjọ ti mo ti mu nwọn jade ti Egipti wá, titi o si fi di oni, bi nwọn ti kọ̀ mi silẹ, ti nwọn si nsin awọn ọlọrun miran, bẹ̃ni nwọn ṣe si ọ pẹlu.

9. Njẹ nitorina gbọ́ ohùn wọn: ṣugbọn lẹhin igbati iwọ ba ti jẹri si wọn tan, nigbana ni ki iwọ ki o si fi iwà ọba ti yio jẹ lori wọn hàn wọn.

10. Samueli si sọ gbogbo ọ̀rọ Oluwa fun awọn enia na ti o mbere ọba lọwọ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. Sam 8