Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 5:8-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Nwọn ranṣẹ nitorina, nwọn si pè gbogbo awọn ijoye Filistini sọdọ wọn, nwọn bere pe, Awa o ti ṣe apoti Ọlọrun Israeli si? Nwọn si dahun pe, Ẹ jẹ ki a gbe apoti Ọlọrun Israeli lọ si Gati. Nwọn si gbe apoti Ọlọrun Israeli na lọ sibẹ.

9. O si ṣe pe, lẹhin igbati nwọn gbe e lọ tan, ọwọ́ Oluwa si wà si ilu na pẹlu iparun nla, o si pọn awọn enia ilu na loju, ati ọmọde ati agbà, nwọn ni iyọdi.

10. Nitorina nwọn rán apoti Ọlọrun lọ si Ekronu. O si ṣe, bi apoti Ọlọrun ti de Ekronu, bẹ̃li awọn enia Ekronu kigbe wipe, nwọn gbe apoti Ọlọrun Israeli tọ̀ ni wá, lati pa wa, ati awọn enia wa.

11. Bẹ̃ni nwọn ranṣẹ, nwọn si pe gbogbo ijoye Filistini jọ, nwọn si wipe, Rán apoti Ọlọrun Israeli lọ, ki ẹ si jẹ ki o tun pada lọ si ipò rẹ̀, ki o má ba pa wa, ati awọn enia wa: nitoriti ipaiya ikú ti wà ni gbogbo ilu na; ọwọ́ Ọlọrun si wuwo gidigidi ni ibẹ.

12. Awọn ọmọkunrin ti kò kú ni a si fi iyọdi pọn loju: igbe ilu na si lọ soke ọrun.

Ka pipe ipin 1. Sam 5