Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 29:6-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Akiṣi si pe Dafidi, o si wi fun u pe, Bi Oluwa ti mbẹ lãye, iwọ jẹ olõtọ ati ẹni ìwa rere loju mi, ni alọ rẹ ati abọ̀ rẹ pẹlu mi li ogun; nitoripe emi ko iti ri buburu kan lọwọ rẹ lati ọjọ ti iwọ ti tọ̀ mi wá, titi o fi di oni yi: ṣugbọn loju awọn ijoye iwọ kò ṣe ẹni ti o tọ́.

7. Njẹ yipada ki o si ma lọ li alafia, ki iwọ ki o má ba ṣe ibanujẹ fun awọn Filistini.

8. Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Kili emi ṣe? kini iwọ si ri lọwọ iranṣẹ rẹ lati ọjọ ti emi ti gbe niwaju rẹ titi di oni yi, ti emi kì yio fi lọ ba awọn ọta ọba ja?

9. Akiṣi si dahun o si wi fun Dafidi pe, Emi mọ̀ pe iwọ ṣe ẹni-rere loju mi, bi angeli Ọlọrun: ṣugbọn awọn ijoye Filistini wi pe, On kì yio ba wa lọ si ogun.

10. Njẹ, nisisiyi dide li owurọ pẹlu awọn iranṣẹ oluwa rẹ ti o ba ọ wá: ki ẹ si dide li owurọ nigbati ilẹ ba mọ́, ki ẹ si ma lọ.

11. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si dide li owurọ lati pada lọ si ilẹ awọn Filistini. Awọn Filistini si goke lọ si Jesreeli.

Ka pipe ipin 1. Sam 29