Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 28:12-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Nigbati obinrin na si ri Samueli, o kigbe lohùn rara: obinrin na si ba Saulu sọrọ pe, Ẽṣe ti iwọ fi tan mi jẹ? nitoripe Saulu ni iwọ iṣe.

13. Ọba si wi fun u pe, Máṣe bẹ̀ru; kini iwọ ri? obinrin na si wi fun Saulu pe, Emi ri ọlọrun kan nṣẹ́ ti ilẹ wá.

14. O si bi i pe, Ẽ ti ri? o si wipe, Ọkunrin arugbo kan li o nṣẹ́ bọ̀; o si fi agbada bora. Saulu si mọ̀ pe, Samueli ni; o si tẹriba, o si wolẹ.

15. Samueli si wi fun Saulu pe, Eṣe ti iwọ fi yọ mi lẹnu lati mu mi wá oke? Saulu si dahun o si wipe, Ipọnju nla ba mi; nitoriti awọn Filistini mba mi jagun, Ọlọrun si kọ̀ mi silẹ, kò si da mi lohùn mọ, nipa ọwọ́ awọn woli, tabi nipa alá; nitorina li emi si ṣe pè ọ, ki iwọ ki ole fi ohun ti emi o ṣe hàn mi.

16. Samueli si wipe, O ti ṣe bi mi lere nigbati o jẹ pe, Oluwa ti kọ̀ ọ silẹ, o si wa di ọta rẹ?

17. Oluwa si ṣe fun ara rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ti ipa ọwọ́ mi sọ: Oluwa si yà ijọba na kuro li ọwọ́ rẹ, o si fi fun aladugbo rẹ, ani Dafidi.

18. Nitoripe iwọ kò gbọ́ ohùn Oluwa, iwọ kò si ṣe iṣẹ ibinu rẹ̀ si Amaleki, nitorina li Oluwa si ṣe nkan yi si ọ loni yi:

19. Oluwa yio si fi Israeli pẹlu iwọ le awọn Filistini lọwọ: li ọla ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ ọkunrin yio pẹlu mi: Oluwa yio si fi ogun Israeli le awọn Filistini lọwọ́.

20. Lojukanna ni Saulu ṣubu lulẹ gbọrọ bi o ti gùn, ẹ̀ru si bà a gidigidi, nitori ọ̀rọ Samueli; agbara kò si si fun u: nitoripe kò jẹun li ọjọ na t'ọsan t'oru.

21. Obinrin na si tọ Saulu wá, o si ri i pe o wà ninu ibanujẹ pupọ, o si wi fun u pe, Wõ, iranṣẹbinrin rẹ ti gbọ́ ohùn rẹ, emi si ti fi ẹmi mi si ọwọ́ mi, emi si ti gbọ́ ọ̀rọ ti iwọ sọ fun mi.

22. Njẹ, nisisiyi, emi bẹ ọ, gbọ́ ohùn iranṣẹbinrin rẹ, emi o si fi onjẹ diẹ siwaju rẹ; si jẹun, iwọ o si li agbara, nigbati iwọ ba nlọ li ọ̀na.

23. Ṣugbọn on kọ̀, o si wipe, Emi kì yio jẹun. Ṣugbọn awọn iranṣẹ rẹ̀, pẹlu obinrin na si rọ̀ ọ; on si gbọ́ ohùn wọn. O si dide kuro ni ilẹ, o si joko lori akete.

24. Obinrin na si ni ẹgbọrọ malu kan ti o sanra ni ile; o si yara, o pa a o si mu iyẹfun, o si pò o, o si fi ṣe akara aiwu.

25. On si mu u wá siwaju Saulu, ati siwaju awọn iranṣẹ rẹ̀; nwọn si jẹun. Nwọn si dide, nwọn lọ li oru na.

Ka pipe ipin 1. Sam 28