Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 27:8-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si goke lọ, nwọn si gbe ogun ti awọn ara Geṣuri, ati awọn ara Gesra, ati awọn ara Amaleki: awọn wọnyi li o si ti ngbe ni ilẹ, na nigba atijọ, bi iwọ ti nlọ si Ṣuri titi o fi de ilẹ Egipti.

9. Dafidi si kọlu ilẹ na, ko si fi ọkunrin tabi obinrin silẹ lãye, o si ko agùtan, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati ibakasiẹ, ati aṣọ, o si yipada o si tọ Akisi wá.

10. Akiṣi si bi i pe, Nibo li ẹnyin gbe rìn si loni? Dafidi si dahun pe, Siha gusu ti Juda ni, ati siha gusun ti Jerameeli, ati siha gusu ti awọn ara Keni:

11. Dafidi kò si da ọkunrin tabi obinrin si lãye, lati mu ihin wá si Gati, wipe, Ki nwọn ki o má ba sọ ọ̀rọ wa nibẹ, pe, Bayi ni Dafidi ṣe, ati bẹ̃ni iṣe rẹ̀ yio si ri ni gbogbo ọjọ ti yio fi joko ni ilu awọn Filistini.

12. Akiṣi si gba ti Dafidi gbọ́, wipe, On ti mu ki Israeli ati awọn enia rẹ̀ korira rẹ̀ patapata, yio si jẹ iranṣẹ mi titi lai.

Ka pipe ipin 1. Sam 27