Dafidi kò si da ọkunrin tabi obinrin si lãye, lati mu ihin wá si Gati, wipe, Ki nwọn ki o má ba sọ ọ̀rọ wa nibẹ, pe, Bayi ni Dafidi ṣe, ati bẹ̃ni iṣe rẹ̀ yio si ri ni gbogbo ọjọ ti yio fi joko ni ilu awọn Filistini.