Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 26:15-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Dafidi si wi fun Abneri pe, Alagbara ọkunrin ki iwọ nṣe ndan? tali o si dabi iwọ ni Israeli? njẹ ẽṣe ti iwọ ko tọju ọba oluwa rẹ? nitori ẹnikan ninu awọn enia na ti wọle wá lati pa ọba oluwa rẹ.

16. Nkan ti iwọ ṣe yi kò dara. Bi Oluwa ti mbẹ, o tọ ki ẹnyin ki o kú, nitoripe ẹnyin ko pa oluwa nyin mọ, ẹni-àmi-ororo Oluwa. Njẹ si wo ibiti ọ̀kọ ọba gbe wà, ati igò omi ti o ti wà nibi timtim rẹ̀.

17. Saulu si mọ̀ ohùn Dafidi, o si wipe, Ohùn rẹ li eyi bi, Dafidi ọmọ mi? Dafidi si wipe, Ohùn mi ni, oluwa mi, ọba.

18. On si wipe, Nitori kini oluwa mi ṣe nlepa iranṣẹ rẹ? kili emi ṣe? tabi ìwa buburu wo li o wà li ọwọ́ mi.

19. Njẹ emi bẹ ọ ọba, oluwa mi, gbọ́ ọ̀rọ iranṣẹ rẹ. Bi Oluwa ba ti ru iwọ soke si mi, jẹ ki on ki o gbà ẹbọ; ṣugbọn bi o ba si ṣepe ọmọ enia ni, ifibu ni ki nwọn ki o jasi niwaju Oluwa; nitori nwọn le mi jade loni ki emi má gbe inu ilẹ ini Oluwa, wipe, Lọ, sin awọn ọlọrun miran.

20. Njẹ máṣe jẹ ki ẹjẹ mi ki o ṣàn silẹ niwaju Oluwa: nitori ọba Israeli jade lati wá itapin bi ẹni ndọdẹ aparo lori oke-nla.

21. Saulu si wipe, Emi ti dẹṣẹ: yipada, Dafidi ọmọ mi: nitoripe emi kì yio wá ibi rẹ mọ, nitoriti ẹmi mi sa ti ṣe iyebiye li oju rẹ loni: wõ, emi ti nhuwa wère mo si ti ṣina jọjọ.

22. Dafidi si dahun, o si wipe, Wo ọ̀kọ̀ ọba! ki o si jẹ ki ọkan ninu awọn ọmọkunrin rekọja wá gbà a.

23. Ki Oluwa ki o san a fun olukuluku ododo rẹ̀ ati otitọ rẹ̀: nitoripe Oluwa ti fi ọ le mi lọwọ loni, ṣugbọn emi ko fẹ nawọ́ mi si ẹni-àmi-ororo Oluwa.

24. Si wõ, gẹgẹ bi ẹmi rẹ ti tobi loni loju mi, bẹni ki ẹmi mi ki o tobi loju Oluwa, ki o si gbà mi lọwọ ibi gbogbo.

25. Saulu si wi fun Dafidi pe, Alabukunfun ni iwọ, Dafidi ọmọ mi: nitõtọ iwọ o si ṣe nkan nla, nitotọ iwọ o si bori. Dafidi si ba ọ̀na rẹ̀ lọ, Saulu si yipada si ibugbe rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. Sam 26