Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 22:15-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Oni li emi o ṣẹṣẹ ma bere li ọwọ́ Ọlọrun fun u bi? ki eyini jinà si mi: ki ọba ki o máṣe ka nkankan si iranṣẹ rẹ̀ lọrùn, tabi si gbogbo idile baba mi: nitoripe iranṣẹ rẹ kò mọ̀ kan ninu gbogbo nkan yi, diẹ tabi pupọ.

16. Ọba si wipe, Ahimeleki, kikú ni iwọ o kú, iwọ, ati gbogbo idile baba rẹ.

17. Ọba si wi fun awọn aṣaju ti ima sare niwaju ọba, ti o duro tì i, pe, Yipada ki ẹ si pa awọn alufa Oluwa; nitoripe ọwọ́ wọn wà pẹlu Dafidi, ati nitoripe, nwọn mọ̀ igbati on sa, nwọn kò si sọ ọ li eti mi. Ṣugbọn awọn iranṣẹ ọba ko si jẹ fi ọwọ́ wọn le awọn alufa Oluwa lati pa wọn.

18. Ọba si wi fun Doegi pe, Iwọ, yipada, ki o si pa awọn alufa. Doegi ara Edomu si yipada, o si kọlu awọn alufa, o si pa li ọjọ na, àrunlelọgọrin enia ti nwọ aṣọ ọgbọ̀ Efodu.

19. O si fi oju ida pa ara Nobu, ilu awọn alufa na ati ọkunrin ati obinrin, ọmọ wẹrẹ, ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, ati malu, ati kẹtẹkẹtẹ, ati agutan.

20. Ọkan ninu awọn ọmọ Ahimeleki ọmọ Ahitubu ti a npè ni Abiatari si bọ́; o si sa asala tọ Dafidi lọ.

21. Abiatari si fi han Dafidi pe, Saulu pa awọn alufa Oluwa tan.

22. Dafidi si wi fun Abiatari pe, emi ti mọ̀ ni ijọ na, nigbati Doegi ara Edomu nì ti wà nibẹ̀ pe, nitotọ yio sọ fun Saulu: nitori mi li a ṣe pa gbogbo idile baba rẹ.

23. Iwọ joko nihin lọdọ mi, máṣe bẹ̀ru, nitoripe ẹniti nwá ẹmi mi, o nwá ẹmi rẹ: ṣugbọn lọdọ mi ni iwọ o wà li ailewu.

Ka pipe ipin 1. Sam 22