Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 21:6-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Bẹ̃ni alufa na si fi akara mimọ́ fun u; nitoriti kò si akara miran nibẹ bikoṣe akara ifihan ti a ti ko kuro niwaju Oluwa, lati fi akara gbigbona sibẹ li ọjọ ti a ko o kuro.

7. Ọkunrin kan ninu awọn iranṣẹ Saulu si mbẹ nibẹ li ọjọ na, ti a ti da duro niwaju Oluwa; orukọ rẹ̀ si njẹ Doegi, ara Edomu olori ninu awọn darandaran Saulu.

8. Dafidi si tun wi fun Ahimeleki pe, Kò si ọ̀kọ tabi idà lọwọ rẹ nihin? nitoriti emi kò mu idà mi, bẹ̃li emi kò mu nkan ijà mi lọwọ, nitoripe iṣẹ ọba na jẹ́ iṣẹ ikanju.

9. Alufa na si wipe, idà Goliati ara Filistini ti iwọ pa li afonifoji Ela ni mbẹ, wõ, a fi aṣọ kan wé e lẹhin Efodu; bi iwọ o ba mu eyini, mu u; kò si si omiran nihin mọ bikoṣe ọkanna. Dafidi si wipe, Kò si eyiti o dabi rẹ̀, fun mi.

10. Dafidi si dide, o si sa ni ijọ na niwaju Saulu, o si lọ sọdọ Akiṣi, ọba Gati.

11. Awọn iranṣẹ Akiṣi si wi fun u pe, Ṣe eyiyi ni Dafidi ọba ilẹ na? nwọn kò ha ti da ti nwọn si gberin nitori rẹ̀ ni ijo, pe, Saulu pa ẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbãrun tirẹ̀?

12. Dafidi si pa ọ̀rọ wọnyi mọ li ọkàn rẹ̀, o si bẹ̀ru Akiṣi ọba Gati gidigidi.

13. On si pa iṣe rẹ̀ dà niwaju wọn, o si sọ ara rẹ̀ di aṣiwere li ọwọ́ wọn, o si nfi ọwọ́ rẹ̀ há ilẹkun oju ọ̀na, o si nwà itọ́ si irungbọn rẹ̀.

14. Nigbana ni Akiṣi wi fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Wõ, ẹnyin ri pe ọkunrin na nhuwà aṣiwere; njẹ nitori kini ẹnyin ṣe mu u tọ̀ mi wá?

15. Mo ha ni aṣiwere fi ṣe? ti ẹnyin fi mu eyi tọ̀ mi wá lati hu iwa aṣiwere niwaju mi? eleyi yio ha wọ inu ile mi?

Ka pipe ipin 1. Sam 21