Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 20:32-39 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Jonatani si da Saulu baba rẹ̀ lohùn, o si wi fun u pe, Nitori kini on o ṣe kú? kili ohun ti o ṣe?

33. Saulu si jù ẹṣín si i lati fi pa a; Jonatani si wa mọ̀ pe baba on ti pinnu rẹ̀ lati pa Dafidi.

34. Bẹ̃ni Jonatani sì fi ibinu dide kuro ni ibi onjẹ, kò si jẹn ní ijọ keji oṣu na: inu rẹ̀ si bajẹ gidigidi fun Dafidi, nitoripe baba rẹ̀ doju tì i.

35. O si ṣe, li owurọ ni Jonatani jade lọ si oko li akoko ti on ati Dafidi ti fi si, ọmọdekunrin kan si wà pẹlu rẹ̀.

36. O si wi fun ọmọdekunrin rẹ̀ pe, sare, ki o si wá ọfà wọnni ti emi o ta. Bi ọmọde na si ti nsare, on si tafa rekọja rẹ̀.

37. Nigbati ọmọdekunrin na si de ibi ọfà ti Jonatani ta, Jonatani si kọ si ọmọdekunrin na, o si wipe, ọfà na ko ha wà niwaju rẹ bi?

38. Jonatani si kọ si ọmọdekunrin na pe, Sare, yara, máṣe duro. Ọmọdekunrin Jonatani si ṣa ọfà wọnni, o si tọ̀ oluwa rẹ̀ wá.

39. Ọmọdekunrin na kò si mọ̀ nkan: ṣugbọn Jonatani ati Dafidi li o mọ̀ ọ̀ran na.

Ka pipe ipin 1. Sam 20