Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 20:12-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Jonatani si wi fun Dafidi pe, Oluwa Ọlọrun Israeli, nigbati mo ba si lu baba mi li ohùn gbọ́ li ọla tabi li ọtunla, si wõ, bi ire ba wà fun Dafidi, ti emi kò ba si ranṣẹ si ọ, ti emi kò si sọ ọ li eti rẹ.

13. Ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ si Jonatani: ṣugbọn bi o ba si ṣe pe o wu baba mi lati ṣe buburu si ọ, emi o si sọ ọ li eti rẹ, emi o si jẹ ki o lọ, iwọ o si lọ li alafia, ki Oluwa ki o si pẹlu rẹ gẹgẹ bi o ti wà pẹlu baba mi.

14. Ki iṣe kiki igbà ti mo wà lãye ni iwọ o si ṣe ãnu Oluwa fun mi, ki emi ki o má kú.

15. Ṣugbọn ki iwọ ki o máṣe mu ãnu rẹ kuro ni ile mi lailai: ki isi ṣe igbati Oluwa ke olukuluku ọtá Dafidi kuro lori ilẹ.

16. Bẹ̃ ni Jonatani bá ile Dafidi da majẹmu wipe, Oluwa yio si bere rẹ̀ lọwọ awọn ọta Dafidi.

Ka pipe ipin 1. Sam 20