Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 19:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Mikali si mu ere, o si tẹ́ ẹ sori akete, o si fi timtim onirun ewurẹ sibẹ fun irọri rẹ̀, o si fi aṣọ bò o.

14. Nigbati Saulu si ran onṣẹ lati mu Dafidi, on si wi fun wọn pe, Kò sàn.

15. Saulu si tun ran awọn onṣẹ na lọ iwo Dafidi, o wi pe, Gbe e goke tọ̀ mi wá ti-akete ti-akete ki emi ki o pa a.

16. Nigbati awọn onṣẹ na de, sa wõ, ere li o si wà lori akete, ati timtim onirun ewurẹ fun irọri rẹ̀.

17. Saulu si wi fun Mikali pe, Eha ti ṣe ti iwọ fi tàn mi jẹ bẹ̃, ti iwọ si fi jọwọ ọta mi lọwọ lọ, ti on si bọ? Mikali si da Saulu lohùn pe, On wi fun mi pe, Jẹ ki emi lọ; ẽṣe ti emi o fi pa ọ?

18. Dafidi si sa, o si bọ, o si tọ Samueli wá ni Rama, o si rò fun u gbogbo eyi ti Saulu ṣe si i. On ati Samueli si lọ, nwọn si ngbe Naoti.

19. A si wi fun Saulu pe, Wõ, Dafidi mbẹ ni Naoti ni Rama.

20. Saulu si ran onṣẹ lati mu Dafidi: nigbati nwọn ri ẹgbẹ awọn wolĩ ti nsọtẹlẹ, ati Samueli ti o duro bi olori wọn, Ẹmi Ọlọrun si bà le awọn onṣẹ Saulu, awọn na si nsọtẹlẹ.

21. A si ro fun Saulu, o si ran onṣẹ miran, awọn na si nsọtẹlẹ. Saulu si tun ran onṣẹ lẹ̃kẹta, awọn na si nsọtẹlẹ.

22. On na si lọ si Rama, o si de ibi kanga nla kan ti o wà ni Seku: o si bere, o si wipe, Nibo ni Samueli ati Dafidi gbe wà? ẹnikan si wipe, Wõ, nwọn mbẹ ni Naoti ni Rama.

23. On si lọ sibẹ si Naoti ni Rama: Ẹmi Ọlọrun si ba le on na pẹlu, o si nlọ, o si nsọtẹlẹ titi o fi de Naoti ni Rama.

Ka pipe ipin 1. Sam 19