Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 19:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SAULU si sọ fun Jonatani ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, pe, ki nwọn ki o pa Dafidi.

2. Ṣugbọn Jonatani ọmọ Saulu fẹràn Dafidi pupọ: Jonatani si sọ fun Dafidi pe, Saulu baba mi nwá ọ̀na ati pa ọ, njẹ, mo bẹ̀ ọ, kiyesi ara rẹ titi di owurọ, ki o si joko nibi ikọ̀kọ, ki o si sa pamọ.

3. Emi o si jade lọ, emi o si duro ti baba mi li oko na nibiti iwọ gbe wà, emi o si ba baba mi sọ̀rọ nitori rẹ; eyiti emi ba si ri, emi o sọ fun ọ.

4. Jonatani si sọ̀rọ Dafidi ni rere fun Saulu baba rẹ̀, o si wi fun u pe, Ki a máṣe jẹ ki ọba ki o ṣẹ̀ si iranṣẹ rẹ̀, si Dafidi; nitori kò ṣẹ̀ ọ, ati nitoripe iṣẹ rẹ̀ dara gidigidi fun ọ.

5. Nitoriti o mu ẹmi rẹ̀ lọwọ rẹ̀, o si pa Filistini na, Oluwa si ṣiṣẹ igbala nla fun gbogbo Israeli: iwọ ri i, o si yọ̀: njẹ, nitori kini iwọ o ṣe dẹṣẹ̀ si ẹjẹ alaiṣẹ, ti iwọ o fi pa Dafidi laiṣẹ?

6. Saulu si gbọ́ ohùn Jonatani: Saulu si bura pe, Bi Oluwa ti wà lãye a ki yio pa a.

7. Jonatani si pe Dafidi, Jonatani si ro gbogbo ọràn na fun u. Jonatani si mu Dafidi tọ Saulu wá, on si wà niwaju rẹ̀, bi igbà atijọ.

8. Ogun si tun wà sibẹ, Dafidi si jade lọ, o si ba awọn Filistini jà, o si pa wọn pupọ; nwọn si sa niwaju rẹ̀.

9. Ẹmi buburu lati ọdọ Oluwa wá si bà le Saulu, o si joko ni ile rẹ̀ ton ti ẹṣín rẹ̀ li lọwọ rẹ̀: Dafidi a si ma fi ọwọ́ rẹ̀ kọrin lara duru.

Ka pipe ipin 1. Sam 19