Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 18:21-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Saulu si wipe, Emi o fi i fun u, yio si jẹ idẹkùn fun u, ọwọ́ awọn Filistini yio si wà li ara rẹ̀. Saulu si wi fun Dafidi pe, Iwọ o wà di ana mi loni, ninu mejeji.

22. Saulu si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ lọ ba Dafidi sọ̀rọ kẹlẹkẹlẹ pe, Kiyesi i, inu ọba dùn si ọ jọjọ, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ li o si fẹ ọ, njẹ nitorina jẹ ana ọba.

23. Awọn iranṣẹ Saulu si sọ̀rọ wọnni li eti Dafidi. Dafidi si wipe, O ha ṣe nkan ti o fẹrẹ loju nyin lati jẹ ana ọba? Talaka li emi ati ẹni ti a kò kà si.

24. Awọn iranṣẹ Saulu si wa irò fun u, pe, Ọrọ bayi ni Dafidi sọ.

25. Saulu si wipe, Bayi li ẹnyin o sọ fun Dafidi, ọba kò sa fẹ ohun-ana kan bikoṣe ọgọrun ẹfa abẹ Filistini, ati lati gbẹsan lara awọn ọta ọba; ṣugbọn Saulu rò ikú Dafidi lati ọwọ́ awọn Filistini wá.

26. Nigbati awọn iranṣẹ rẹ̀ si sọ̀rọ wọnyi fun Dafidi, ohun na si dara li oju Dafidi lati di ana ọba: ọjọ kò si iti pe.

27. Dafidi si dide, o lọ, on ati awọn ọmọkunrin rẹ̀, o si pa igba ọmọkunrin ninu awọn Filistini; Dafidi si mu ẹfa abẹ wọn wá, nwọn si kà wọn pe fun ọba, ki on ki o le jẹ ana ọba. Saulu si fi Mikali ọmọ rẹ obinrin fun u li aya.

28. Saulu si ri o si mọ̀ pe, Oluwa wà pẹlu Dafidi, Mikali ọmọbinrin Saulu si fẹ ẹ.

29. Saulu si bẹ̀ru Dafidi siwaju ati siwaju: Saulu si wa di ọtá Dafidi titi.

30. Awọn ọmọ-alade Filistini si jade lọ: o si ṣe, lẹhin igbati nwọn lọ, Dafidi si huwa ọlọgbọ́n ju gbogbo awọn iranṣẹ Saulu lọ; orukọ rẹ̀ si ni iyìn jọjọ.

Ka pipe ipin 1. Sam 18