Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 18:1-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati o ba Saulu sọ̀rọ tan, ọkàn Jonatani si fà mọ ọkàn Dafidi, Jonatani si fẹ ẹ bi ontikararẹ̀.

2. Saulu si mu u sọdọ lọjọ na, ko si jẹ ki o lọ sọdọ baba rẹ̀ mọ.

3. Jonatani on Dafidi si ba ara wọn mulẹ; nitoripe o fẹ ẹ gẹgẹ bi o ti fẹ ọkàn ara rẹ̀.

4. Jonatani si bọ aṣọ ileke ti o wà li ara rẹ̀ o si fi i fun Dafidi, ati ihamọra rẹ̀, titi de idà rẹ̀, ọrun rẹ̀, ati amure rẹ̀.

5. Dafidi a si ma lọ si ibikibi ti Saulu rán a, a ma huwa ọlọgbọ́n: Saulu si fi i jẹ olori ogun, o si dara loju gbogbo awọn enia, ati pẹlupẹlu loju awọn iranṣẹ Saulu.

6. O si ṣe, bi nwọn ti de, nigbati Dafidi ti ibi ti o gbe pa Filistini na bọ̀, awọn obinrin si ti gbogbo ilu Israeli jade wá, nwọn nkọrin nwọn si njo lati wá ipade Saulu ọba, ti awọn ti ilù, ati ayọ̀, ati duru.

7. Awọn obinrin si ndá, nwọn si ngbe orin bi nwọn ti nṣire, nwọn si nwipe, Saulu pa ẹgbẹgbẹrun tirẹ̀, Dafidi si pa ẹgbẹgbarun tirẹ̀.

8. Saulu si binu gidigidi, ọ̀rọ na si buru loju rẹ̀ o si wipe, Nwọn fi ẹgbẹgbarun fun Dafidi, nwọn si fi ẹgbẹgbẹrun fun mi, kili o si kù fun u bikoṣe ijọba.

9. Saulu si nfi oju ilara wo Dafidi lati ọjọ na lọ.

10. O si ṣe ni ijọ keji, ti ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun wá si ba le Saulu, on si sọtẹlẹ li arin ile; Dafidi si fi ọwọ́ rẹ̀ ṣire lara duru bi igba atẹhinwa; ẹṣín kan mbẹ lọwọ Saulu.

11. Saulu si sọ ẹṣín ti o wà lọwọ rẹ̀ na; o si wipe, Emi o pa Dafidi li apa mọ́ ogiri. Dafidi si yẹra kuro niwaju rẹ lẹ̃meji.

12. Saulu si bẹ̀ru Dafidi, nitoripe Oluwa wà pẹlu rẹ̀, ṣugbọn Oluwa kọ̀ Saulu.

13. Nitorina Saulu si mu u kuro lọdọ rẹ̀, o si fi i jẹ olori ogun ẹgbẹrun kan, o si nlọ, o si mbọ̀ niwaju awọn enia na.

14. Dafidi si ṣe ọlọgbọ́n ni gbogbo iṣe rẹ̀; Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.

15. Nigbati Saulu ri pe, o nhuwa ọgbọ́n gidigidi, o si mbẹ̀ru rẹ̀.

Ka pipe ipin 1. Sam 18