Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 17:51-58 Yorùbá Bibeli (YCE)

51. Dafidi si sure, o si duro lori Filistini na, o si mu ida rẹ̀, o si fà a yọ ninu akọ̀ rẹ̀, o si pa a, o si fi idà na bẹ́ ẹ li ori. Nigbati awọn Filistini si ri pe akikanju wọn kú, nwọn si sa.

52. Awọn ọkunrin Israeli ati ti Juda si dide, nwọn si ho yè, nwọn si nle awọn Filistini lọ, titi nwọn fi de afonifoji kan, ati si ojubode Ekronu. Awọn ti o gbọgbẹ ninu awọn Filistini si ṣubu lulẹ li ọ̀na Ṣaaraimu, ati titi de Gati, ati Ekronu.

53. Awọn ọmọ Israeli si pada lati ma lepa awọn Filistini, nwọn si ba budo wọn jẹ.

54. Dafidi si gbe ori Filistini na, o si mu u wá si Jerusalemu; ṣugbọn o fi ihamọra rẹ̀ si inu agọ rẹ̀.

55. Nigbati Saulu si ri Dafidi ti nlọ pade Filistini na, o si bi Abneri oloriogun pe, Abneri, ọmọ tani ọmọde yi iṣe? Abneri si dahun pe, bi ọkàn rẹ ti wà lãye, ọba, emi kò mọ̀.

56. Ọba si wipe, Iwọ bere ọmọ tali ọmọde na iṣe?

57. Bi Dafidi si ti ti ibi ti o gbe pa Filistini na bọ̀, Abneri si mu u wá siwaju Saulu, ti on ti ori Filistini na lọwọ rẹ̀.

58. Saulu si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ ọmọde yi iṣe? Dafidi si da a li ohùn pe, Emi li ọmọ Jesse iranṣẹ rẹ ara Betlehemu.

Ka pipe ipin 1. Sam 17