Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 17:4-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Akikanju kan si jade lati ibudo awọn Filistini wá, orukọ rẹ̀ ama jẹ Goliati, ara Gati, ẹniti giga rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹfa ati ibu atẹlẹwọ kan.

5. On si ni akoro idẹ kan li ori rẹ̀, o si wọ̀ ẹ̀wu kan ti a fi idẹ pẹlẹbẹ pẹlẹbẹ ṣe, ìwọn ẹwu na si jẹ ẹgbẹdọgbọn Ṣekeli idẹ.

6. On si ni kobita idẹ li ẹsẹ rẹ̀, ati apata idẹ kan larin ejika rẹ̀.

7. Ọpa ọ̀kọ rẹ̀ si dabi igi awọn awunṣọ, ati ori ọ̀kọ rẹ̀ si jẹ ẹgbẹta oṣuwọn sekeli irin: ẹnikan ti o ru awà kan si nrin niwaju rẹ̀.

8. O si duro o si kigbe si ogun Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin jade lati tẹgun? ṣe Filistini kan li emi iṣe? ẹnyin si jẹ ẹrú Saulu. Ẹnyin yan ọkunrin kan fun ara nyin, ki ẹnyin si jẹ ki o sọkale tọ̀ mi wá.

9. Bi on ba le ba mi ja, ki o si pa mi, nigbana li awa o di ẹrú nyin: ṣugbọn bi emi ba le ṣẹgun rẹ̀, ti emi si pa a, nigbana ni ẹnyin a si di ẹrú wa, ẹnyin o si ma sìn wa.

10. Filistini na si wipe, Emi fi ija lọ̀ ogun Israeli li oni: fi ọkunrin kan fun mi, ki awa mejeji jumọ ba ara wa jà.

11. Nigbati Saulu ati gbogbo Israeli gbọ́ ọ̀rọ Filistini na, nwọn damu, ẹ̀ru nlanla si ba wọn.

12. Dafidi si jẹ ọmọ ara Efrata na ti Betlehemu Juda, orukọ ẹniti ijẹ Jesse; o si ni ọmọ mẹjọ, o si jẹ arugbo larin enia li ọjọ Saulu.

13. Awọn mẹta ti o dàgba ninu awọn ọmọ Jesse, si tọ Saulu lẹhin lọ si oju ijà: orukọ awọn ọmọ mẹtẹta ti o lọ si ibi ijà si ni Eliabu, akọbi, atẹle rẹ̀ si ni Abinadabu, ẹkẹta si ni Ṣamma.

14. Dafidi si ni abikẹhin: awọn ẹgbọ́n iwaju rẹ̀ mẹtẹta ntọ̀ Saulu lẹhin.

Ka pipe ipin 1. Sam 17