Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 15:3-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Lọ nisisiyi ki o si kọlu Amaleki, ki o si pa gbogbo nkan wọn li aparun, má si ṣe da wọn si; ṣugbọn pa ati ọkunrin ati obinrin wọn, ọmọ kekere ati awọn ti o wà li ẹnu ọmu, malu ati agutan, ibakasiẹ ati kẹtẹkẹtẹ.

4. Saulu si ko awọn enia na jọ pọ̀ o si ka iye wọn ni Telaimu, nwọn si jẹ ogun ọkẹ awọn ọkunrin ogun ẹlẹsẹ, pẹlu ẹgbarun awọn ọkunrin Juda.

5. Saulu si wá si ilu-nla kan ti awọn ara Amaleki, o si ba dè wọn li afonifoji kan.

6. Saulu si wi fun awọn Keniti pe, Ẹ lọ, yẹra kuro larin awọn ara Amaleki, ki emi ki o má ba run nyin pẹlu wọn: nitoripe ẹnyin ṣe ore fun gbogbo awọn ọmọ Israeli nigbati nwọn goke ti Egipti wá. Awọn Keniti yẹra kuro larin Amaleki.

7. Saulu si kọlu Amaleki lati Hafila titi iwọ o fi de Ṣuri, ti o wà li apa keji Egipti.

8. O si mu Agagi Ọba Amaleki lãye, o si fi oju ida run gbogbo awọn enia na.

9. Ṣugbọn Saulu ati awọn enia na da Agagi si, ati eyi ti o dara julọ ninu agutan ati ninu malu, ati ohun eyi ti o dara tobẹ̃ ninu wọn, ati ọdọ-agutan abọpa, ati gbogbo nkan ti o dara; nwọn kò si fẹ pa wọn run: ṣugbọn gbogbo nkan ti kò dara ti kò si nilari ni nwọn parun patapata.

Ka pipe ipin 1. Sam 15