Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 13:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SAULU jọba li ọdun kan; nigbati o si jọba ọdun meji lori Israeli,

2. Saulu si yan ẹgbẹ̃dogun ọmọkunrin fun ara rẹ̀ ni Israeli; ẹgbã si wà lọdọ Saulu ni Mikmaṣi ati li oke-nla Beteli; ẹgbẹrun si wà lọdọ Jonatani ni Gibea ti Benjamini; o si rán awọn enia ti o kù olukuluku si agọ rẹ̀.

3. Jonatani si pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini ti o wà ninu ile olodi ni Geba, awọn Filistini si gbọ́. Saulu fun ipè yi gbogbo ilẹ na ka, wipe, Jẹ ki awọn Heberu gbọ́.

4. Gbogbo Israeli si gbọ́ pe Saulu pa ẹgbẹ ogun awọn Filistini, Israeli si di irira fun awọn Filistini. Awọn enia na si pejọ lẹhin Saulu lati lọ si Gilgali.

5. Awọn Filistini kó ara wọn jọ lati ba Israeli jà, ẹgbã-mẹ̃dogun kẹkẹ, ẹgbãta ọkunrin ẹlẹṣin, enia si pọ̀ bi yanrin leti okun; nwọn si goke, nwọn do ni Mikmaṣi ni iha ila õrun Bet-Afeni.

6. Awọn ọkunrin Israeli si ri pe, nwọn wà ninu ipọnju (nitoripe awọn enia na wà ninu ìhamọ) nigbana ni awọn enia na fi ara pamọ ninu iho, ati ninu panti, ninu apata, ni ibi giga, ati ninu kanga gbigbẹ.

7. Omiran ninu awọn Heberu goke odo Jordani si ilẹ Gadi ati Gileadi. Bi o ṣe ti Saulu, on wà ni Gilgali sibẹ, gbogbo enia na si nwariri lẹhin rẹ̀.

8. O si duro ni ijọ meje, de akoko ti Samueli dá fun u; ṣugbọn Samueli kò wá si Gilgali, awọn enia si tuka kuro li ọdọ rẹ̀.

9. Saulu si wipe, Mu ẹbọ sisun ati ẹbọ irẹpọ̀ na fun mi wá, o si ru ẹbọ sisun na.

10. O si ṣe, bi o ti ṣe ẹbọ ọrẹ ati ẹbọ sisun wọnni pari, si kiye si i, Samueli de; Saulu si jade lati lọ pade rẹ̀, ki o le ki i.

11. Samueli si bi i pe, Kini iwọ ṣe yi? Saulu si dahùn pe, Nitoriti emi ri pe awọn enia na ntuka kuro lọdọ mi, iwọ kò si wá li akoko ọjọ ti o dá, awọn Filistini si ko ara wọn jọ ni Mikmaṣi.

12. Nitorina li emi ṣe wipe, Nisisiyi li awọn Filistini yio sọkalẹ tọ mi wá si Gilgali, bẹ̃li emi ko iti tù Oluwa loju; emi si tì ara mi si i, mo si ru ẹbọ sisun na.

Ka pipe ipin 1. Sam 13