Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 12:17-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Oni ki ọjọ ikore ọka bi? emi o kepe Oluwa, yio si ran ãra ati ojò; ẹnyin o si mọ̀, ẹnyin o si ri pe iwabuburu nyin pọ̀, ti ẹnyin ṣe li oju Oluwa ni bibere ọba fun ara nyin.

18. Samueli si kepe Oluwa, Oluwa si ran ãra ati ojò ni ọjọ na: gbogbo enia si bẹru Oluwa pupọ ati Samueli.

19. Gbogbo enia si wi fun Samueli pe, Gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ fun awọn iranṣẹ rẹ, ki awa ki o má ba kú: nitori ti awa ti fi buburu yi kun gbogbo ẹṣẹ wa ni bibere ọba fun ara wa.

20. Samueli si wi fun awọn enia na pe, Ẹ má bẹ̀ru: ẹnyin ti ṣe gbogbo buburu yi: sibẹ ẹ má pada lẹhin Oluwa, ẹ ma fi gbogbo ọkàn nyin sin Oluwa.

21. Ẹ máṣe yipada; nitori yio jasi itẹle ohun asan lẹhin, eyi ti kì yio ni ere; bẹ̃ni kì yio si gbanila; nitori asan ni nwọn.

22. Nitoriti Oluwa kì yio kọ̀ awọn enia rẹ̀ silẹ nitori orukọ rẹ̀ nla: nitoripe o wu Oluwa lati fi nyin ṣe enia rẹ̀.

23. Pẹlupẹlu bi o ṣe ti emi ni, ki a má ri i pe emi si dẹṣẹ̀ si Oluwa ni didẹkun gbadura fun nyin: emi o si kọ́ nyin li ọ̀na rere ati titọ.

24. Ṣugbọn ẹ bẹ̀ru Oluwa, ki ẹ si fi gbogbo ọkàn nyin sin i lododo: njẹ, ẹ ronu ohun nlanla ti o ṣe fun nyin.

25. Ṣugbọn bi ẹnyin ba hu ìwa buburu sibẹ, ẹnyin o ṣegbé t'ẹnyin t'ọba nyin.

Ka pipe ipin 1. Sam 12