Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 11:13-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Saulu si wi pe, a kì yio pa ẹnikẹni loni yi; nitoripe loni li Oluwa ṣiṣẹ igbala ni Israeli.

14. Nigbana ni Samueli wi fun awọn enia na pe, Wá, ki a lọ si Gilgali, ki a le tun ijọba na ṣe nibẹ.

15. Gbogbo enia na si lọ si Gilgali; nibẹ ni nwọn gbe fi Saulu jọba niwaju Oluwa ni Gilgali: nibẹ ni nwọn gbe ru ẹbọ irẹpọ̀ niwaju Oluwa; nibẹ ni Saulu ati gbogbo awọn ọkunrin Israeli si yọ ayọ̀ nlanla.

Ka pipe ipin 1. Sam 11