Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 7:24-40 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Ọmọ rẹ̀ obinrin ni Sera, ẹniti o tẹ̀ Bet-horoni dó, ti isalẹ ati ti òke, ati Usseni Ṣera.

25. Refa si ni ọmọ rẹ̀ ọkunrin, Reṣefu pẹlu, ati Tela ọmọ rẹ̀, ati Tahani ọmọ rẹ̀.

26. Laadani ọmọ rẹ̀, Ammihudi ọmọ rẹ̀, Eliṣama ọmọ rẹ̀.

27. Nuni ọmọ rẹ̀, Joṣua ọmọ rẹ̀,

28. Ati awọn ini ati ibugbe wọn ni Beteli, ati ilu rẹ̀, ati niha ìla-õrùn Naarani, niha ìwọ-õrùn Geseri pẹlu ilu rẹ̀: Ṣekemu pẹlu ati ilu rẹ̀, titi de Gasa ilu rẹ̀:

29. Ati leti ilu awọn ọmọ Manasse, Betṣeani, ati ilu rẹ̀, Taanaki ati ilu rẹ̀, Megiddo ati ilu rẹ̀, Dori ati ilu rẹ̀. Ninu awọn wọnyi li awọn ọmọ Josefu, ọmọ Israeli, ngbe.

30. Awọn ọmọ Aṣeri: Imna, ati Iṣua, ati Iṣuai, ati Beria, ati Sera, arabinrin wọn.

31. Awọn ọmọ Beria: Heberi, ati Malkieli, ti iṣe baba Birsafiti.

32. Heberi si bi Jafleti, ati Ṣomeri, ati Hotamu, ati Ṣua, arabinrin wọn.

33. Ati awọn ọmọ Jafleti: Pasaki, ati Bimhali, ati Aṣfati. Wọnyi li awọn omọ Jafleti.

34. Awọn ọmọ Ṣameri: Ahi, ati Roga, Jehubba, ati Aramu.

35. Awọn ọmọ arakunrin rẹ̀ Helemu: Sofa, ati Imna, ati Ṣeleṣi, ati Amali.

36. Awọn ọmọ Sofa; Sua, ati Harneferi, ati Ṣuali, ati Beri, ati Imra,

37. Beseri, ati Hodi, ati Ṣamma, ati Ṣilṣa, ati Itrani, ati Beera.

38. Ati awọn ọmọ Jeteri: Jefunne, ati Pispa, ati Ara.

39. Ati awọn ọmọ Ulla: Ara, ati Hanieli, ati Resia.

40. Gbogbo awọn wọnyi li awọn ọmọ Aṣeri, awọn olori ile baba wọn, aṣayan alagbara akọni enia, olori ninu awọn ijoye. Iye awọn ti a kà yẹ fun ogun, ati fun ijà ni idile wọn jẹ, ẹgbã mẹtala ọkunrin.

Ka pipe ipin 1. Kro 7