Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 5:12-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Joeli olori, ati Ṣafamu àtẹle, ati Jaanai, ati Ṣafati ni Baṣani.

13. Ati awọn arakunrin wọn ti ile awọn baba wọn ni Mikaeli, ati Meṣullamu, ati Ṣeba, ati Jorai, ati Jakani, ati Sia, ati Heberi, meje.

14. Wọnyi li awọn ọmọ Abihaili, ọmọ Huri, ọmọ Jaroa, ọmọ Gileadi, ọmọ Mikaeli, ọmọ Jeṣiṣai, ọmọ Jado, ọmọ Busi;

15. Adi, ọmọ Abdieli, ọmọ Guni, olori ile awọn baba wọn.

16. Nwọn si ngbe Gileadi ni Baṣani, ati ninu awọn ilu rẹ̀, ati ninu gbogbo igberiko Ṣaroni, li àgbegbe wọn.

17. Gbogbo wọnyi li a kà nipa itan-idile, li ọjọ Jotamu ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọba Israeli,

18. Awọn ọmọ Rubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ninu awọn ọkunrin alagbara ti nwọn ngbé asà ati idà, ti nwọn si nfi ọrun tafà, ti nwọn si mòye ogun, jẹ ọkẹ meji enia o le ẹgbẹrinlelogún o di ogoji, ti o jade lọ si ogun na.

19. Nwọn si ba awọn ọmọ Hagari jagun, pẹlu Jeturi, ati Nefiṣi ati Nadabu.

20. A si ràn wọn lọwọ si wọn, a si fi awọn ọmọ Hagari le wọn lọwọ, ati gbogbo awọn ti o wà pẹlu wọn: nitoriti nwọn kepè Ọlọrun li ogun na, on si gbọ́ ẹ̀bẹ wọn: nitoriti nwọn gbẹkẹ wọn le e.

Ka pipe ipin 1. Kro 5