Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 4:7-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Ati awọn ọmọ Hela ni Sereti, ati Jesoari, ati Etnani.

8. Kosi si bi Anubu, ati Sobeba, ati awọn idile Aharheli, ọmọ Harumu.

9. Jabesi si ṣe ọlọla jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ: iya rẹ̀ si pe orukọ rẹ̀ ni Jabesi, wipe, Nitoriti mo bi i pẹlu ibanujẹ.

10. Jabesi si ké pè Ọlọrun Israeli, wipe, Iwọ iba jẹ bukún mi nitõtọ, ki o si sọ àgbegbe mi di nla, ki ọwọ rẹ ki o si wà pẹlu mi, ati ki iwọ ki o má si jẹ ki emi ri ibi, ki emi má si ri ibinujẹ! Ọlọrun si mu ohun ti o tọrọ ṣẹ.

Ka pipe ipin 1. Kro 4