Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 4:1-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN ọmọ Juda; Faresi, Hesroni, ati Karmi, ati Huri, ati Ṣobali.

2. Reaiah ọmọ Ṣobali si bi Jahati; Jahati si bi Ahumai, ati Lahadi. Wọnyi ni idile awọn ara Sora.

3. Awọn wọnyi li o ti ọdọ baba Etamu wá; Jesreeli ati Jisma, ati Jidbaṣi: orukọ arabinrin wọn si ni Selelponi:

4. Ati Penueli ni baba Gedori, ati Eseri baba Huṣa. Wọnyi ni awọn ọmọ Huri, akọbi Efrata, baba Betlehemu.

5. Aṣuri baba Tekoa si li aya meji, Hela ati Naara.

6. Naara si bi Ahusamu, ati Heferi, ati Temeni, ati Ahaṣtari fun u. Wọnyi li awọn ọmọ Naara.

7. Ati awọn ọmọ Hela ni Sereti, ati Jesoari, ati Etnani.

8. Kosi si bi Anubu, ati Sobeba, ati awọn idile Aharheli, ọmọ Harumu.

9. Jabesi si ṣe ọlọla jù awọn arakunrin rẹ̀ lọ: iya rẹ̀ si pe orukọ rẹ̀ ni Jabesi, wipe, Nitoriti mo bi i pẹlu ibanujẹ.

10. Jabesi si ké pè Ọlọrun Israeli, wipe, Iwọ iba jẹ bukún mi nitõtọ, ki o si sọ àgbegbe mi di nla, ki ọwọ rẹ ki o si wà pẹlu mi, ati ki iwọ ki o má si jẹ ki emi ri ibi, ki emi má si ri ibinujẹ! Ọlọrun si mu ohun ti o tọrọ ṣẹ.

11. Kelubu arakunrin Ṣua si bi Mehiri, ti iṣe baba Eṣtoni.

12. Eṣtoni si bi Bet-rafa, ati Pasea, ati Tehinna baba ilu Nahaṣi. Wọnyi li awọn ọkunrin Reka,

13. Ati awọn ọmọ Kenasi; Otnieli, ati Seraiah: ati awọn ọmọ Otnieli; Hatati.

Ka pipe ipin 1. Kro 4