Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 26:24-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Ati Ṣebueli ọmọ Gerṣomu, ọmọ Mose, ni onitọju iṣura.

25. Ati awọn arakunrin rẹ̀ nipa Elieseri, Rehabiah ọmọ rẹ̀, ati Jesaiah ọmọ rẹ̀, ati Joramu, ọmọ rẹ̀, ati Sikri ọmọ rẹ̀, ati Ṣelomiti ọmọ rẹ̀.

26. Ṣelomiti yi ati awọn arakunrin rẹ̀ li o wà lori iṣura ohun iyà-si-mimọ́, ti Dafidi ọba ati awọn olori baba, awọn ijoye lori ẹgbẹgbẹrun, ati ọrọrun, ati awọn olori ogun ti yà-si-mimọ́.

27. Lati inu ikogun ti a kó li ogun, ni nwọn yà si mimọ́ lati ma fi ṣe itọju ile Oluwa.

28. Ati gbogbo eyiti Samueli, ariran, ati Saulu, ọmọ Kiṣi, ati Abneri ọmọ Neri, ati Joabu ọmọ Seruiah, yà si mimọ́; gbogbo ohun ti a ba ti yà si mimọ́, ohun na mbẹ li ọwọ Ṣelomiti, ati awọn arakunrin rẹ̀.

29. Ninu awọn ọmọ Ishari, Kenaniah ati awọn ọmọ rẹ̀ li o jẹ ijoye ati onidajọ fun iṣẹ ilu lori Israeli.

30. Ninu awọn ọmọ Hebroni, Hasabiah ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn akọni enia, ẽdẹgbẹsan li awọn alabojuto Israeli nihahin Jordani niha iwọ-õrun, fun gbogbo iṣẹ Oluwa, ati fun ìsin ọba.

31. Ninu awọn ọmọ Hebroni ni Jerijah olori, ani ninu awọn ọmọ Hebroni, gẹgẹ bi idile ati iran awọn baba rẹ̀. Li ogoji ọdun ijọba Dafidi, a wá wọn, a si ri ninu wọn, awọn alagbara akọni enia ni Jaseri ti Gileadi.

32. Ati awọn arakunrin rẹ̀, awọn akọni enia, jẹ ẹgbã o le ẽdẹgbẹrin: gbogbo wọn jẹ awọn olori baba ti Dafidi ọba fi ṣe olori lori awọn ọmọ Rubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, fun gbogbo ọ̀ran ti Ọlọrun ati ti ọba.

Ka pipe ipin 1. Kro 26