Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 24:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ bi a ti pín awọn ọmọ Aaroni ni wọnyi. Awọn ọmọ Aaroni; Nadabu ati Abihu, Eleasari, ati Itamari.

2. Ṣugbọn Nadabu ati Abihu kú ṣaju baba wọn, nwọn kò si li ọmọ: nitorina ni Eleasari ati Itamari fi ṣiṣẹ alufa.

3. Dafidi si pin wọn, ati Sadoku ninu awọn ọmọ Eleasari, ati Ahimeleki ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi iṣẹ wọn ninu ìsin wọn.

4. A si ri awọn ọkunrin ti o nṣe olori ninu awọn ọmọ Eleasari jù ti inu awọn ọmọ Itamari lọ, bayi li a si pin wọn. Ninu awọn ọmọ Eleasari, ọkunrin mẹrindilogun li o nṣe olori ni ile baba wọn, ati mẹjọ ninu awọn ọmọ Itamari, gẹgẹ bi ile baba wọn.

5. Bayi li a fi iṣẹkeké pin wọn, iru kan mọ ikeji pẹlu; nitori awọn olori ibi mimọ́, ati olori ti Ọlọrun wà ninu awọn ọmọ Eleasari, ati ninu awọn ọmọ Itamari.

6. Ati Ṣemaiah ọmọ Nataneeli akọwe, ọkan ninu awọn ọmọ Lefi kọ wọn niwaju ọba, ati awọn olori, ati Sadoku alufa, ati Ahimeleki, ọmọ Abiatari, ati niwaju olori awọn baba awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi: a mu ile baba kan fun Eleasari, a si mu ọkan fun Itamari.

7. Njẹ iṣẹkeké ekini jade fun Jehoiaribu, ekeji fun Jedaiah,

8. Ẹkẹta fun Harimu, ẹkẹrin fun Seorimu,

Ka pipe ipin 1. Kro 24