Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 17:14-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Ṣugbọn emi o fi idi rẹ̀ kalẹ ninu ile mi ati ninu ijọba mi lailai, a o si fi idi itẹ rẹ̀ mulẹ lailai.

15. Gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi, ati gẹgẹ bi gbogbo iran yi, bẹ̃ni Natani sọ fun Dafidi.

16. Dafidi ọba si wá, o si joko niwaju Oluwa, o si wipe, Tali emi Oluwa Ọlọrun, ati kini ile mi, ti iwọ si mu mi de ihinyi?

17. Ohun kekere si li eyi li oju rẹ, Ọlọrun: iwọ si ti sọ pẹlu sipa ile iranṣẹ rẹ fun akokò jijin ti mbọ, o si ka mi si bi iṣe enia giga, Oluwa Ọlọrun.

18. Kini Dafidi le tun ma sọ pẹlu fun ọ niti ọlá ti a bù fun iranṣẹ rẹ? iwọ sa mọ̀ iranṣẹ rẹ.

19. Oluwa, nitoriti iranṣẹ rẹ, ati gẹgẹ bi ti inu rẹ, ni iwọ ti ṣe gbogbo ohun nlanla yi, ni sisọ gbogbo nkan nla wọnyi di mimọ̀.

20. Oluwa, kò si ẹniti o dabi rẹ bẹ̃ni kò si Ọlọrun miran lẹhin rẹ, gẹgẹ bi gbogbo eyi ti awa ti fi eti wa gbọ́.

21. Orilẹ-ède kan wo li o wà li aiye ti o dabi enia rẹ, Israeli, ti Ọlọrun lọ irapada lati ṣe enia on tikararẹ, lati ṣe orukọ fun ara rẹ nipa ohun ti o tobi ti o si lẹ̀ru, ni lile awọn orilẹ-ède jade kuro niwaju awọn enia rẹ, ti iwọ ti rapada lati Egipti jade wá?

22. Nitori awọn enia rẹ Israeli li o ti ṣe li enia rẹ titi lai; iwọ Oluwa, si di Ọlọrun wọn.

23. Njẹ nisisiyi, Oluwa! jẹ ki ọ̀rọ ti iwọ ti sọ niti iranṣẹ rẹ, ati niti ile rẹ̀ ki o fi idi mulẹ lailai, ki iwọ ki o si ṣe bi iwọ ti wi.

24. Ani, jẹ ki o fi idi mulẹ, ki a le ma gbé orukọ rẹ ga lailai, wipe, Oluwa awọn ọmọ ogun li Ọlọrun Israeli, ani Ọlọrun fun Israeli; si jẹ ki ile Dafidi iranṣẹ rẹ ki o fi idi mulẹ niwaju rẹ.

25. Nitori iwọ, Ọlọrun mi, ti ṣi iranṣẹ rẹ li eti pe, Iwọ o kọ́ ile kan fun u: nitorina ni iranṣẹ rẹ ri i lati gbadua niwaju rẹ.

26. Njẹ nisisiyi Oluwa, Iwọ li Ọlọrun, iwọ si ti sọ ọ̀rọ ore yi fun iranṣẹ rẹ;

Ka pipe ipin 1. Kro 17