Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 17:1-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O SI ṣe, bi Dafidi ti joko ninu ile rẹ̀, ni Dafidi sọ fun Natani woli pe, Wò o, emi ngbe inu ile kedari, ṣugbọn apoti ẹri majẹmu Oluwa ngbe abẹ aṣọ-tita.

2. Nigbana ni Natani wi fun Dafidi pe, Ṣe ohun gbogbo ti mbẹ ni inu rẹ; nitoriti Ọlọrun wà pẹlu rẹ.

3. O si ṣe li oru kanna ni ọ̀rọ Ọlọrun tọ Natani wá, wipe,

4. Lọ, si sọ fun Dafidi iranṣẹ mi pe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun mi lati ma gbe.

5. Nitori emi kò ti igbe inu ile lati ọjọ ti mo ti mu Israeli gòke wá titi fi di oni yi; ṣugbọn emi nlọ lati agọ de agọ, ati lati ibugbe kan de keji.

6. Nibikibi ti mo ti nrin larin gbogbo Israeli, emi ha sọ̀rọ kan fun ọkan ninu awọn onidajọ Israeli, ti emi ti paṣẹ fun lati ma bọ awọn enia mi, emi ha ti wipe, Ẽṣe ti ẹnyin kò fi kọ́ ile igi kedari fun mi bi?

7. Njẹ nitorina bayi ni iwọ o wi fun Dafidi iranṣẹ mi, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, Emi mu ọ kuro ni pápá oko-tutu, ani kuro lati ma tọ agutan lẹhin, ki iwọ ki o le ma ṣe olori awọn enia mi Israeli.

8. Emi si ti wà pẹlu rẹ ni ibikibi ti iwọ ba lọ, emi si ti ké gbogbo awọn ọta rẹ kuro niwaju rẹ, emi o si ṣe ọ li olorukọ kan, bi orukọ awọn enia nla ti o ti wà li aiye.

9. Emi o si yan ibi kan fun Israeli awọn enia mi, emi o si gbìn wọn, ki nwọn le má gbe ipò wọn, a kì yio si ṣì wọn mọ; bẹ̃ni ọmọ buburu kì yio yọ wọn lẹnu mọ, bi ti atijọ;

10. Ati bi igba ti emi ti fi enia jẹ onidajọ lori awọn enia mi Israeli. Ati pẹlu emi o ṣẹgun gbogbo awọn ọta rẹ. Pẹlupẹlu mo ti sọ fun ọ pe, Oluwa yio kọle kan fun ọ.

11. Yio si ṣe, nigbati ọjọ rẹ ba pe, ti iwọ o lọ pẹlu awọn baba rẹ, ni emi o gbé iru-ọmọ rẹ dide lẹhin rẹ, ti yio jẹ ọkan ninu awọn ọmọ rẹ ọkunrin; emi o si fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ.

Ka pipe ipin 1. Kro 17