Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 16:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BẸ̀NI nwọn mu apoti ẹri Ọlọrun wá, nwọn si fi si arin agọ na ti Dafidi pa fun u: nwọn si ru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia niwaju Ọlọrun,

2. Nigbati Dafidi si ti pari riru ẹbọ sisun ati ẹbọ alafia tan, o sure fun awọn enia li orukọ Oluwa.

3. O si fi fun gbogbo enia Israeli, ati ọkunrin ati obinrin fun olukulùku iṣu akara kan, ati ekiri ẹran kan, ati akara didùn kan.

4. O si yan ninu awọn ọmọ Lefi lati ma jọsin niwaju apoti ẹri Oluwa, ati lati ṣe iranti, ati lati dupẹ, ati lati yìn Oluwa Ọlọrun Israeli:

5. Asafu ni olori, ati atẹle rẹ̀ ni Sekariah, Jeieli, ati Ṣemiramotu, ati Jehieli, ati Mattitiah, ati Eliabu, ati Benaiah, ati Obed-Edomu: ati Jeieli pẹlu psalteri ati pẹlu duru; ṣugbọn Asafu li o nlù kimbali kikan;

6. Benaiah pẹlu ati Jahasieli awọn alufa pẹlu ipè nigbagbogbo niwaju apoti ẹri ti majẹmu Ọlọrun.

7. Li ọjọ na ni Dafidi kọ́ fi orin mimọ́ yi le Asafu lọwọ lati dupẹ lọwọ Oluwa.

8. Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa, ẹ pè orukọ rẹ̀, ẹ fi iṣẹ rẹ̀ hàn ninu awọn enia.

9. Ẹ kọrin si i, ẹ kọ́ orin mimọ́ si i, ẹ ma sọ̀rọ gbogbo iṣẹ iyanu rẹ̀.

10. Ẹ ma ṣogo li orukọ rẹ̀ mimọ́; jẹ ki ọkàn awọn ti nwá Oluwa ki o yọ̀.

11. Ẹ ma wá Oluwa, ati ipa rẹ̀, ma wá oju rẹ̀ nigbagbogbo.

12. Ẹ ma ranti iṣẹ iyanu rẹ̀ ti o ti ṣe, iṣẹ àmi rẹ̀, ati idajọ ẹnu rẹ̀;

Ka pipe ipin 1. Kro 16