Bayi ni gbogbo Israeli gbé apoti ẹri majẹmu Oluwa gòke wá pẹlu iho ayọ̀, ati iró fère, ati pẹlu ipè, ati kimbali, psalteri ati duru si ndún kikankikan.