Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 14:11-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Bẹ̃ni nwọn gòke lọ si Baal-perasimu; Dafidi si kọlù wọn nibẹ. Dafidi si wipe, Ọlọrun ti ti ọwọ mi yà lu awọn ọta mi bi yiya omi: nitorina ni nwọn ṣe npè ibẹ na ni Baal-perasimu.

12. Nwọn si fi awọn orisa wọn silẹ nibẹ, Dafidi si wipe, ki a fi iná sun wọn.

13. Awọn ara Filistia si tun tẹ ara wọn kakiri ni afonifoji.

14. Nitorina ni Dafidi tun bère lọwọ Ọlọrun: Ọlọrun si wi fun u pe, Máṣe gòke tọ̀ wọn; yipada kuro lọdọ wọn, ki o si ja lu wọn niwaju igi mulberi.

15. Yio si ṣe, nigbati iwọ ba gbọ́ iro ẹsẹ lòke igi mulberi, nigbana ni ki iwọ ki o gbogun jade: nitori Ọlọrun jade ṣaju rẹ lọ lati kọlù ogun awọn ara Filistia.

16. Dafidi si ṣe gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ fun u: nwọn si kọlù ogun awọn ara Filistia lati Gibeoni titi de Gaseri.

17. Okiki Dafidi si kan yi gbogbo ilẹ ka. Oluwa si mu ki ẹ̀ru rẹ̀ ki o ba gbogbo orilẹ-ède.

Ka pipe ipin 1. Kro 14